Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì, àwọn olórí wọn àti àwọn alàgbà àti àwọn olùkọ́ni ní òfin péjọ sí Jerusalẹmu. Àti Annasi olórí àlùfáà, àti Kaiafa, àti Johanu, àti Aleksanderu, àti iye àwọn tí i ṣe ìbátan olórí àlùfáà. Wọ́n mú Peteru àti Johanu dúró níwájú wọn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Nípa agbára tàbí orúkọ wo ni ẹ̀yin fi ṣe èyí?” Nígbà náà ni Peteru kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin olórí àti ẹ̀yin alàgbà àwọn ènìyàn! Bí ó bá ṣe pé a ń wádìí wa lónìí ní tí iṣẹ́ rere ti a ṣe lára abirùn náà, bí a ti ṣe mú ọkùnrin yìí láradá, Kí èyí yé gbogbo yín àti gbogbo ènìyàn Israẹli pé, ni orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, tí ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, tí Ọlọ́run jí dìde kúrò nínú òkú, nípa rẹ̀ ni ọkùnrin yìí fi dúró níwájú yín ni ara dídá-ṣáṣá. Èyí ni “ ‘òkúta tí a ti ọwọ́ ẹ̀yin ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀, tí ó sì di pàtàkì igun ilé.’ Kò sì sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn; nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run ti a fi fún ni nínú ènìyàn, nípa èyí tí a lè fi gbà wá là.” Nígbà tí wọ́n sì kíyèsi ìgboyà Peteru àti Johanu, tí wọ́n mọ̀ pé, aláìkẹ́kọ̀ọ́ àti òpè ènìyàn ni wọn, ẹnu yà wọ́n, wọ́n sì wòye pé, wọ́n ti ń bá Jesu gbé.
Kà Ìṣe àwọn Aposteli 4
Feti si Ìṣe àwọn Aposteli 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Ìṣe àwọn Aposteli 4:5-13
7 Days
Nearly everyone agrees that this world is broken. But what if there’s a solution? This seven-day Easter plan begins with the unique experience of the thief on the cross and considers why the only real answer to brokenness is found in the execution of an innocent man: Jesus, the Son of God.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò