Ìṣe àwọn Aposteli 4:31-33

Ìṣe àwọn Aposteli 4:31-33 YCB

Nígbà tí wọ́n gbàdúrà tan, ibi tí wọ́n gbé péjọpọ̀ sí mì tìtì; gbogbo wọn sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, wọ́n sì ń fi ìgboyà sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìjọ àwọn tí ó gbàgbọ́ sì wà ní ọkàn kan àti inú kan; kò sì ṣí ẹnìkan tí ó wí pé ohun kan nínú ohun ìní rẹ̀ jẹ́ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n gbogbo wọn ní ohun gbogbo ní ìṣọ̀kan. Agbára ńlá ni àwọn aposteli sì fi ń jẹ́rìí àjíǹde Jesu Olúwa, oore-ọ̀fẹ́ púpọ̀ sì wà lórí gbogbo wọn.