2 Tẹsalonika 2:3-7

2 Tẹsalonika 2:3-7 YCB

Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó tàn yín jẹ ní ọ̀nàkọnà, nítorí pé ọjọ́ náà kì yóò dé, bí kò ṣe pé ìṣọ̀tẹ̀ bá kọ́ ṣẹlẹ̀, tí a sì fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, tí í ṣe ọmọ ègbé. Òun yóò lòdì sí, yóò sì gbé ara rẹ̀ ga sí gbogbo ohun tí a ń pè ní Ọlọ́run tàbí tí a ń sìn, dé ibi pé yóò gbé ara rẹ̀ jókòó nínú tẹmpili Ọlọ́run, tí yóò sì pe ara rẹ̀ ní Ọlọ́run. Ṣé ẹ̀yin kò rántí pé nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín, mo ń sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún un yín. Àti pé nísinsin yìí, ẹ̀yin mọ ohun tí ń dá a dúró, kí a bá a lè fi í hàn ní àkókò rẹ̀ gan an. Nítorí agbára ìkọ̀kọ̀ ẹni ẹ̀ṣẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́; ṣùgbọ́n ẹni tí ń dènà yóò máa ṣe bẹ́ẹ̀ títí a ó fi mú un kúrò ní ọ̀nà.