Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikẹni tàn nyin jẹ lọnakọna; nitoripe ọjọ na ki yio de, bikoṣepe ìyapa nì ba kọ́ de, ki a si fi ẹni ẹ̀ṣẹ nì hàn, ti iṣe ọmọ ègbé; Ẹniti nṣòdì, ti o si ngbé ara rẹ̀ ga si gbogbo ohun ti a npè li Ọlọrun, tabi ti a nsin; tobẹ ti o joko ni tẹmpili Ọlọrun, ti o nfi ara rẹ̀ hàn pe Ọlọrun li on. Ẹnyin kò ranti pe, nigbati mo wà lọdọ nyin, mo nsọ̀ nkan wọnyi fun nyin? Ati nisisiyi ẹnyin mọ ohun ti o nṣe idena, ki a le ba fi i hàn li akokò rẹ̀. Nitoripe ohun ijinlẹ ẹ̀ṣẹ ti nṣiṣẹ ná: kìki pe ẹnikan wà ti nṣe idena nisisiyi, titi a ó fi mu u ti ọ̀na kuro.
Kà II. Tes 2
Feti si II. Tes 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: II. Tes 2:3-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò