2 Samuẹli 3:1-5

2 Samuẹli 3:1-5 YCB

Ogun náà sì pẹ́ títí láàrín ìdílé Saulu àti ìdílé Dafidi: agbára Dafidi sì ń pọ̀ sí i, ṣùgbọ́n ìdílé Saulu ń rẹ̀yìn sí i. Dafidi sì bí ọmọkùnrin ní Hebroni: Amnoni ni àkọ́bí rẹ̀ tí Ahinoamu ará Jesreeli bí fún un. Èkejì rẹ̀ sì ni Kileabu, tí Abigaili aya Nabali ará Karmeli bí fún un; ẹ̀kẹta sì ni Absalomu ọmọ tí Maaka ọmọbìnrin Talmai ọba Geṣuri bí fún un. Ẹ̀kẹrin sì ni Adonijah ọmọ Haggiti; àti ẹ̀karùnún ni Ṣefatia ọmọ Abitali; Ẹ̀kẹfà sì ni Itreamu, tí Egla aya Dafidi bí fún un.