Àwọn ọmọ wòlíì sọ fún Eliṣa pé, “Wò ó, ní ibi tí a ti pàdé pẹ̀lú rẹ, ó kéré fún wa. Jẹ́ kí àwa kí ó lọ sí Jordani, ní ibi tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti le rí ọ̀pá kan, jẹ́ kí àwa kí ó kọ́lé síbẹ̀ fún wa láti gbé.” Ó sì wí pé, “lọ.” Nígbà náà ni ọ̀kan lára wọn wí pé, “Kí ó wù ọ́, èmí bẹ̀ ọ́, láti bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ lọ?” Eliṣa dá a lóhùn pé “Èmi yóò lọ,” Ó sì lọ pẹ̀lú wọn. Wọ́n sì lọ sí Jordani wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gé igi Bí ọ̀kan ṣe gé igi náà, àáké irin náà bọ́ sínú omi, ó kígbe sókè pé, “O! Olúwa mi, mo yá a ni!” Ènìyàn Ọlọ́run sì béèrè pé, “Níbo ni ó bọ́ sí?” Nígbà tí ó fi ibẹ̀ hàn án, Eliṣa gé igi kan ó sì jù ú síbẹ̀, ó sì mú irin náà fò lójú omi.
Kà 2 Ọba 6
Feti si 2 Ọba 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: 2 Ọba 6:1-6
13 Days
Elisha is one of the most fascinating people found in God’s word. He was a prophet whose faith and miracles seem almost ridiculous. During this 13-day reading plan you will read through the life of Elisha and learn from his example of what life can look like when you let go and decide to live with ridiculous faith.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò