Ní ọjọ́ kan àwọn ọmọ àwọn wolii tí wọ́n wà lábẹ́ àkóso Eliṣa sọ fún un pé, “Ibi tí à ń gbé kéré jù fún wa. Jọ̀wọ́ fún wa ní ààyè láti lọ gé igi ní etí odò Jọdani láti fi kọ́ ilé mìíràn tí a óo máa gbé.” Eliṣa dáhùn pé, “Ó dára, ẹ máa lọ.” Ọ̀kan ninu wọn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó bá àwọn lọ, ó sì gbà bẹ́ẹ̀. Gbogbo wọn jọ lọ, nígbà tí wọ́n dé etí odò Jọdani, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gé igi. Bí ọ̀kan ninu wọn ti ń gé igi, lójijì, irin àáké tí ó ń lò yọ bọ́ sinu odò. Ó kígbe pé, “Yéè! Oluwa mi, a yá àáké yìí ni!” Eliṣa bèèrè pé, “Níbo ni ó bọ́ sí?” Ọkunrin náà sì fi ibẹ̀ hàn án. Eliṣa gé igi kan, ó jù ú sinu omi, irin àáké náà sì léfòó lójú omi.
Kà ÀWỌN ỌBA KEJI 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ÀWỌN ỌBA KEJI 6:1-6
13 Days
Elisha is one of the most fascinating people found in God’s word. He was a prophet whose faith and miracles seem almost ridiculous. During this 13-day reading plan you will read through the life of Elisha and learn from his example of what life can look like when you let go and decide to live with ridiculous faith.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò