2 Kọrinti 8:10-15

2 Kọrinti 8:10-15 YCB

Àti nínú èyí ni mo fi ìmọ̀ràn mi fún yín: nítorí èyí ṣe àǹfààní fún yín, ẹ̀yin tí ó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ níwọ̀n ọdún tí ó kọjá, kì í ṣe láti ṣe nǹkan, ṣùgbọ́n láti fẹ́ pẹ̀lú. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ parí ṣíṣe iṣẹ́ náà pẹ̀lú; kí ó ba à lè ṣe pé, bí ìpinnu fún ṣíṣe ti wà, bẹ́ẹ̀ ni kí ìparí sì wà láti inú agbára yín. Nítorí bí ìpinnu bá wà ṣáájú, ó jásí ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí ohun tí ènìyàn bá ní, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun tí kò ní. Nítorí èmi kò fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn wà ní ìrọ̀rùn, kí ó sì jẹ́ ìpọ́njú fún yín, ṣùgbọ́n pé nípa mímú dọ́gba, Ní àkókò yìí, pé kí àníṣẹ́kù yín lè ṣe déédé àìní wọn, kí àníṣẹ́kù tiwọn pẹ̀lú ba à lè ṣe déédé àìní yín: kí ìmúdọ́gba ba à lè wà. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹni tí ó kó púpọ̀ kò ní púpọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó kó ìwọ̀nba kò ní kéré jù.”