1 Kọrinti 6:12-14

1 Kọrinti 6:12-14 BMYO

“Ohun gbogbo ní ó tọ́ fún mi,” ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní èrè. “Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi,” ṣùgbọ́n èmi kì yóò jẹ́ kí ohunkóhun ṣe olórí fun mi. “Oúnjẹ fún inú àti inú fún oúnjẹ,” ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò fi òpin sí méjèèjì, ara kì í ṣe fún ìwà àgbèrè ṣíṣe, ṣùgbọ́n fún Olúwa, àti Olúwa fún ara náà. Nínú agbára rẹ̀, Ọlọ́run jí Olúwa dìde kúrò nínú òkú bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò jí àwa náà dìde.