Sek 9:9-11

Sek 9:9-11 YBCV

Yọ̀ gidigidi, iwọ ọmọbinrin Sioni; ho, Iwọ ọmọbinrin Jerusalemu: kiye si i, Ọba rẹ mbọ̀wá sọdọ rẹ: ododo li on, o si ni igbalà; o ni irẹ̀lẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ, ani ọmọ kẹtẹkẹtẹ. Emi o si ke kẹkẹ́ kuro ni Efraimu, ati ẹṣin kuro ni Jerusalemu, a o si ké ọrun ogun kuro: yio si sọ̀rọ alafia si awọn keferi: ijọba rẹ̀ yio si jẹ lati okun de okun, ati lati odo titi de opin aiye. Ni tirẹ pẹlu, emi o fi ẹjẹ majẹmu rẹ rán awọn igbèkun rẹ jade kuro ninu ihò ti kò li omi.