Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; gẹgẹ bi mo ti rò lati ṣẹ́ nyin niṣẹ, nigbati awọn baba nyin mu mi binu, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti emi kò si ronupiwadà. Bẹ̃li emi si ti rò ọjọ wọnyi lati ṣe rere fun Jerusalemu, ati fun ile Juda: ẹ má bẹ̀ru. Wọnyi ni nkan ti ẹnyin o ṣe: Ẹ sọ̀rọ otitọ, olukuluku si ẹnikeji rẹ̀; ṣe idajọ tõtọ ati alafia ni bodè nyin wọnni. Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o rò ibi li ọkàn rẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀; ẹ má fẹ ibura eke: nitori gbogbo wọnyi ni mo korira, li Oluwa wi. Ọ̀rọ Oluwa awọn ọmọ-ogun si tọ̀ mi wá wipe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe; Ãwẹ̀ oṣù kẹrin, ati ti oṣù karun, ati ãwẹ̀ oṣù keje, ati ti ẹkẹwa, yio jẹ ayọ̀, ati didùn inu, ati apejọ ariya fun ile Juda; nitorina ẹ fẹ́ otitọ ati alafia. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe; Awọn enia yio sa tún wá, ati ẹniti yio gbe ilu-nla pupọ. Awọn ẹniti ngbe ilu-nla kan yio lọ si omiran, wipe, Ẹ jẹ ki a yára lọ igbadura niwaju Oluwa, ati lati wá Oluwa awọn ọmọ-ogun: emi pẹlu o si lọ. Nitõtọ ọ̀pọlọpọ enia, ati awọn alagbara orilẹ-ède yio wá lati wá Oluwa awọn ọmọ-ogun ni Jerusalemu; ati lati gbadura niwaju Oluwa. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, li ọjọ wọnni yio ṣẹ, ni ọkunrin mẹwa lati inu gbogbo ède ati orilẹ-ède yio dì i mú, ani yio dì eti aṣọ ẹniti iṣe Ju mu, wipe, A o ba ọ lọ, nitori awa ti gbọ́ pe, Ọlọrun wà pẹlu rẹ.
Kà Sek 8
Feti si Sek 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Sek 8:14-23
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò