Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; gẹgẹ bi mo ti rò lati ṣẹ́ nyin niṣẹ, nigbati awọn baba nyin mu mi binu, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti emi kò si ronupiwadà. Bẹ̃li emi si ti rò ọjọ wọnyi lati ṣe rere fun Jerusalemu, ati fun ile Juda: ẹ má bẹ̀ru. Wọnyi ni nkan ti ẹnyin o ṣe: Ẹ sọ̀rọ otitọ, olukuluku si ẹnikeji rẹ̀; ṣe idajọ tõtọ ati alafia ni bodè nyin wọnni. Ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o rò ibi li ọkàn rẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀; ẹ má fẹ ibura eke: nitori gbogbo wọnyi ni mo korira, li Oluwa wi.
Kà Sek 8
Feti si Sek 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Sek 8:14-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò