Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, Mu ninu igbèkun, ninu awọn ti Heldai, ti Tobijah, ati ti Jedaiah, ti o ti Babiloni de, ki iwọ si wá li ọjọ kanna, ki o si wọ ile Josiah ọmọ Sefaniah lọ; Ki o si mu fàdakà ati wurà, ki o si fi ṣe ade pupọ̀, ki o si gbe wọn kà ori Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa: Si sọ fun u pe, Bayi ni Oluwa awọn ọmọ-ogun sọ wipe, Wò ọkunrin na ti orukọ rẹ̀ njẹ ẸKA; yio si yọ ẹka lati abẹ rẹ̀ wá, yio si kọ́ tempili Oluwa; On ni yio si kọ́ tempili Oluwa; on ni yio si rù ogo, yio si joko yio si jọba lori itẹ rẹ̀; on o si jẹ alufa lori itẹ̀ rẹ̀; ìmọ alafia yio si wà lãrin awọn mejeji. Ade wọnni yio si wà fun Helemu, ati fun Tobijah, ati fun Jedaiah, ati fun Heni, ọmọ Sefaniah, fun iranti ni tempili Oluwa.
Kà Sek 6
Feti si Sek 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Sek 6:9-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò