Sek 12:11-14

Sek 12:11-14 YBCV

Li ọjọ na li ọ̀fọ nlanlà yio wà ni Jerusalemu, gẹgẹ bi ọ̀fọ Hadadrimmoni li afonifoji Megiddoni. Ilẹ na yio ṣọ̀fọ, idile idile lọtọ̀tọ; idile Dafidi lọ́tọ̀; ati awọn aya wọn lọ́tọ̀; idile Natani lọ́tọ̀, ati awọn aya wọn lọtọ̀. Idile Lefi lọ́tọ̀, ati awọn aya wọn lọ́tọ̀; idile Ṣimei lọ́tọ̀, ati awọn aya wọn lọ́tọ̀. Gbogbo awọn idile ti o kù, idile idile lọtọ̀tọ, ati awọn aya wọn lọ́tọ̀.