Oluwa si wi fun mi pe, Tún mu ohun-elò oluṣọ agutan aṣiwere kan sọdọ rẹ. Nitori kiye si i, Emi o gbe oluṣọ-agutan kan dide ni ilẹ na, ti kì yio bẹ̀ awọn ti o ṣegbé wò, ti kì yio si wá eyi ti o yapa: ti kì yio ṣe awotan eyi ti o ṣẹ́, tabi kì o bọ́ awọn ti o duro jẹ: ṣugbọn on o jẹ ẹran eyi ti o li ọ̀ra, yio si fà ẽkanna wọn ya pẹrẹpẹ̀rẹ. Egbe ni fun oluṣọ agutan asan na ti o fi ọwọ́-ẹran silẹ! idà yio wà li apá rẹ̀, ati li oju ọ̀tun rẹ̀: apá rẹ̀ yio gbẹ patapata, oju ọ̀tun rẹ̀ yio si ṣõkùnkun biribiri.
Kà Sek 11
Feti si Sek 11
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Sek 11:15-17
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò