Sek 10:4-7

Sek 10:4-7 YBCV

Lati ọdọ rẹ̀ ni igun ti jade wá, lati ọdọ rẹ̀ ni iṣo ti wá, lati ọdọ rẹ̀ ni ọrun ogun ti wá, lati ọdọ rẹ̀ ni awọn akoniṣiṣẹ gbogbo ti wá. Nwọn o si dabi awọn alagbara, ti ntẹ́ ẹrẹ̀ ita ni mọlẹ li ogun: nwọn o si jagun, nitori Oluwa wà pẹlu wọn nwọn o si doju tì awọn ti ngùn ẹṣin. Emi o si mu ile Juda le, emi o si gbà ile Josefu là, emi o si tún mu wọn joko; nitori mo ti ṣãnu fun wọn, nwọn o si dabi ẹnipe emi kò ti ta wọn nù: nitori emi ni Oluwa Ọlọrun wọn, emi o si gbọ́ ti wọn. Efraimu yio si ṣe bi alagbara, ọkàn wọn yio si yọ̀ bi ẹnipe nipa ọti-waini: ani awọn ọmọ wọn yio ri i, nwọn o si yọ̀, inu wọn o si dùn si Oluwa.