Tit 3:4-8

Tit 3:4-8 YBCV

Ṣugbọn nigbati ìṣeun Ọlọrun Olugbala wa ati ifẹ rẹ̀ si enia farahan, Kì iṣe nipa iṣẹ ti awa ṣe ninu ododo ṣugbọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀ li o gbà wa là, nipa ìwẹnu atúnbi ati isọdi titun Ẹmí Mimọ́, Ti o dà si wa lori lọpọlọpọ nipasẹ Jesu Kristi Olugbala wa; Ki a le dá wa lare nipa ore-ọfẹ rẹ̀, ki a si le sọ wa di ajogún gẹgẹ bi ireti ìye ainipẹkun. Otitọ li ọ̀rọ na, emi si nfẹ ki iwọ ki o tẹnumọ nkan wọnyi gidigidi, ki awọn ti o gbà Ọlọrun gbọ́ le mã tọju ati ṣe iṣẹ rere. Nkan wọnyi dara, nwọn si ṣe anfani fun enia.