Tani eyi ti ngòke lati aginju wá, ti o fi ara tì olufẹ rẹ̀? mo ji ọ dide labẹ igi eleso: nibẹ ni iya rẹ gbe bi ọ si, nibẹ li ẹniti o bi ọ gbe bi ọ si. Gbe mi ka aiya rẹ bi edidi, bi edidi le apá rẹ: nitori ifẹ lagbara bi ikú; ijowu si le bi isa-okú; jijo rẹ̀ dabi jijo iná, ani ọwọ iná Oluwa. Omi pupọ kò le paná ifẹ, bẹ̃ni kikún omi kò le gbá a lọ, bi enia fẹ fi gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ fun ifẹ, a o kẹgàn rẹ̀ patapata. Awa ni arabinrin kekere kan, on kò si ni ọmú: kili awa o ṣe fun arabinrin wa li ọjọ ti a o ba fẹ ẹ? Bi on ba ṣe ogiri, awa o kọ́ ile-odi fadaka le e lori: bi on ba si ṣe ẹnu-ọ̀na, awa o fi apako kedari dí i. Ogiri ni mi, ọmú mi sì dabi ile-iṣọ: nigbana loju rẹ̀ mo dabi ẹniti o ri alafia. Solomoni ni ọgba-àjara kan ni Baalhamoni; o fi ọgba-àjara na ṣe ọ̀ya fun awọn oluṣọ; olukuluku ni imu ẹgbẹrun fadaka wá nipò eso rẹ̀. Ọgba-àjara mi, ti iṣe temi, o wà niwaju mi: iwọ Solomoni yio ni ẹgbẹrun fadaka, ati awọn ti nṣọ eso na yio ni igba. Iwọ ti ngbe inu ọgbà, awọn ẹgbẹ rẹ fetisi ohùn rẹ: mu mi gbọ́ ọ pẹlu. Yara, olufẹ mi, ki iwọ ki o si dabi abo egbin tabi ọmọ agbọnrin lori òke õrùn didùn.
Kà O. Sol 8
Feti si O. Sol 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Sol 8:5-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò