Ti olufẹ mi li emi iṣe, ifẹ rẹ̀ si mbẹ si mi. Wá, olufẹ mi, jẹ ki a lọ si pápa; jẹ ki a wọ̀ si iletò wọnni. Jẹ ki a dide lọ sinu ọgba-àjara ni kutukutu; jẹ ki a wò bi àjara ruwe, bi itanná àjara ba là, ati bi igi granate ba rudi: nibẹ li emi o fi ifẹ mi fun ọ. Awọn eso mandraki fun ni li õrùn, li ẹnu-ọ̀na wa ni onirũru eso ti o wunni, ọtun ati ogbologbo, ti mo ti fi pamọ́ fun ọ, iwọ olufẹ mi.
Kà O. Sol 7
Feti si O. Sol 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Sol 7:10-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò