Ẹsẹ rẹ ti li ẹwà to ninu bata, iwọ ọmọ-alade! orike itan rẹ dabi ohun ọṣọ́, iṣẹ ọwọ ọlọgbọ́n oniṣọna. Iwọ́ rẹ dabi ago ti kò ṣe alaini ọti, ara rẹ dabi okiti alikama ti a fi lili yika. Ọmú rẹ mejeji dabi abo ọmọ agbọnrin meji ti iṣe ìbejì. Ọrùn rẹ dabi ile iṣọ ehin-erin; oju rẹ dabi adagun ni Heṣboni, lẹba ẹnu-bode Batrabbimu: imú rẹ dabi ile-iṣọ Lebanoni ti o kọju si ihà Damasku. Ori rẹ dabi Karmeli lara rẹ, ati irun ori rẹ bi purpili; a fi aidì irun rẹ di ọba mu. O ti li ẹwà to, o si ti dara to, iwọ olufẹ mi ninu adùn ifẹ! Iduro rẹ yi dabi igi ọ̀pẹ ati ọmú rẹ bi ṣiri eso àjara. Mo ni, emi o gùn ọ̀pẹ lọ, emi o di ẹka rẹ̀ mu: pẹlupẹlu nisisiyi ọmú rẹ pẹlu yio dabi ṣiri àjara, ati õrùn imú rẹ bi eso appili; Ati ẹnu rẹ bi ọti-waini ti o dara jù, ti o sọkalẹ kẹlẹkẹlẹ fun olufẹ mi, ti o nmu ki etè awọn ti o sùn ki o sọ̀rọ. Ti olufẹ mi li emi iṣe, ifẹ rẹ̀ si mbẹ si mi.
Kà O. Sol 7
Feti si O. Sol 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Sol 7:1-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò