Iwọ yanju, olufẹ mi, bi Tirsa, o li ẹwà bi Jerusalemu, ṣugbọn o li ẹ̀ru bi ogun pẹlu ọpagun. Mu oju rẹ kuro lara mi nitori nwọn bori mi: irun rẹ si dabi ọwọ́ ewurẹ ti o dubulẹ ni Gileadi. Ehin rẹ dabi ọwọ́ agutan ti ngòke lati ibi iwẹ̀ wá, ti olukuluku wọn bi ìbejì, kò si si ọkan ti o yàgan ninu wọn. Bi ẹ̀la eso-pomegranate kan ni ẹrẹkẹ rẹ ri lãrin iboju rẹ. Ọgọta ayaba ni mbẹ, ati ọgọrin àle, ati awọn wundia lainiye. Ọkan ni adaba mi, alailabawọn mi; on nikanṣoṣo ni ti iya rẹ̀, on ni ãyo ẹniti o bi i. Awọn ọmọbinrin ri i, nwọn si sure fun u; ani awọn ayaba ati awọn àle, nwọn si yìn i. Tali ẹniti ntàn jàde bi owurọ, ti o li ẹwà bi oṣupa, ti o mọ́ bi õrun, ti o si li ẹ̀ru bi ogun pẹlu ọpagun? Emi sọkalẹ lọ sinu ọgba eso igi, lati ri awọn ẹka igi tutu afonifoji, ati lati ri bi ajara ba ruwe, ati bi igi-granate ba rudi. Ki emi to mọ̀, ọkàn mi gbe mi ka ori kẹkẹ́ Amminadibu. Pada, pada, Ṣulamite; pada, pada, ki awa ki o le wò ọ. Ẽṣe ti ẹnyin fẹ wò Ṣulamite bi ẹnipe orin ijó Mahanaimu.
Kà O. Sol 6
Feti si O. Sol 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Sol 6:4-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò