Emi sùn, ṣugbọn ọkàn mi ji, ohùn olufẹ mi ni nkànkun, wipe: Ṣilẹkun fun mi, arabinrin mi, olufẹ mi, adaba mi, alailabawọn mi: nitori ori mi kún fun ìri, ati ìdi irun mi fun kikán oru. Mo ti bọ́ awọtẹlẹ mi; emi o ti ṣe gbe e wọ̀? mo ti wẹ̀ ẹsẹ̀ mi; emi o ti ṣe sọ wọn di aimọ́? Olufẹ mi nawọ rẹ̀ lati inu ihò ilẹkùn, inu mi sì yọ si i. Emi dide lati ṣilẹkun fun olufẹ mi, ojia si nkán lọwọ mi, ati ojia olõrùn didùn ni ika mi sori idimu iṣikà. Mo ṣilẹkun fun olufẹ mi; ṣugbọn olufẹ mi ti fà sẹhin, o si ti lọ: aiya pá mi nigbati o sọ̀rọ, mo wá a, ṣugbọn emi kò ri i, mo pè e, ṣugbọn on kò da mi lohùn. Awọn oluṣọ ti nrìn ilu kiri ri mi, nwọn lù mi, nwọn sì ṣa mi lọgbẹ, awọn oluṣọ gbà iborùn mi lọwọ mi. Mo fi nyin bu, ẹnyin ọmọbinrin Jerusalemu, bi ẹnyin ba ri olufẹ mi, ki ẹ wi fun u pe, aisan ifẹ nṣe mi.
Kà O. Sol 5
Feti si O. Sol 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Sol 5:2-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò