Tani eyi ti nti ijù jade wá bi ọwọ̀n ẽfin, ti a ti fi ojia ati turari kùn lara, pẹlu gbogbo ipara olõrun oniṣowo? Wo akete rẹ̀, ti iṣe ti Solomoni; ọgọta akọni enia li o yi i ka ninu awọn akọni Israeli. Gbogbo wọn li o di idà mu, nwọn gbọ́n ọgbọ́n ogun: olukulùku kọ́ idà rẹ̀ nitori ẹ̀ru li oru. Solomoni, ọba, ṣe akete nla fun ara rẹ̀ lati inu igi Lebanoni. O fi fadaka ṣe ọwọ̀n rẹ̀, o fi wura ṣe ibi ẹhin rẹ̀, o fi elese aluko ṣe ibujoko rẹ̀, inu rẹ̀ li o fi ifẹ tẹ́ nitori awọn ọmọbinrin Jerusalemu.
Kà O. Sol 3
Feti si O. Sol 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: O. Sol 3:6-10
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò