Ohùn olufẹ mi! sa wò o, o mbọ̀, o nfò lori awọn òke, o mbẹ lori awọn òke kékeké.
Olufẹ mi dabi abo egbin, tabi ọmọ agbọnrin: sa wò o, o duro lẹhin ogiri wa, o yọju loju ferese, o nfi ara rẹ̀ hàn loju ferese ọlọnà.
Olufẹ mi sọ̀rọ, o si wi fun mi pe, Dide, olufẹ mi, arẹwà mi kanna, ki o si jade kalọ.
Sa wò o, ìgba otutu ti kọja, òjo ti da, o si ti lọ.
Awọn itanna eweko farahàn lori ilẹ; akoko ikọrin awọn ẹiyẹ de, a si gbọ ohùn àdaba ni ilẹ wa.
Igi ọ̀pọtọ so eso titun, awọn àjara funni ni õrun daradara nipa itanná wọn. Dide, olufẹ mi, arẹwà mi kanna, ki o si jade kalọ.
Adaba mi, ti o wà ninu pàlapala okuta, ni ibi ìkọkọ okuta, jẹ ki emi ri oju rẹ, jẹ ki emi gbọ́ ohùn rẹ; nitori didùn ni ohùn rẹ, oju rẹ si li ẹwà.
Mu awọn kọ̀lọkọlọ fun wa, awọn kọ̀lọkọlọ kékeké ti mba àjara jẹ: nitori àjara wa ni itanná.
Olufẹ mi ni temi, emi si ni tirẹ̀: o njẹ lãrin awọn lili.
Titi ìgba itura ọjọ, titi ojiji yio fi salọ, yipada, olufẹ mi, ki iwọ ki o si dabi abo egbin, tabi ọmọ agbọnrin lori awọn oke Beteri.