O. Sol 1:1-3

O. Sol 1:1-3 YBCV

ORIN awọn orin ti iṣe ti Solomoni. Jẹ ki o fi ifẹnukonu ẹnu rẹ̀ kò mi li ẹnu nitori ifẹ rẹ sàn jù ọti-waini lọ. Nitoriti õrun ikunra rere rẹ, orukọ rẹ dabi ikunra ti a tú jade, nitorina ni awọn wundia ṣe fẹ ọ.