Rut 4:11-13

Rut 4:11-13 YBCV

Gbogbo awọn enia ti o wà li ẹnu-bode, ati awọn àgbagba, si wipe, Awa ṣe ẹlẹri. Ki OLUWA ki o ṣe obinrin na ti o wọ̀ ile rẹ bi Rakeli ati bi Lea, awọn meji ti o kọ ile Israeli: ki iwọ ki o si jasi ọlọlá ni Efrata, ki o si jasi olokikí ni Betilehemu. Ki ile rẹ ki o si dabi ile Peresi, ẹniti Tamari bi fun Juda, nipa irú-ọmọ ti OLUWA yio fun ọ lati ọdọ ọmọbinrin yi. Boasi si mú Rutu, on si di aya rẹ̀; nigbati o si wọle tọ̀ ọ, OLUWA si mu ki o lóyun, o si bi ọmọkunrin kan.