Rut 1:15-17

Rut 1:15-17 YBCV

On si wipe, Kiyesi i, orogun rẹ pada sọdọ awọn enia rẹ̀, ati sọdọ oriṣa rẹ̀: iwọ pada tẹlé orogun rẹ. Rutu si wipe, Máṣe rọ̀ mi lati fi ọ silẹ, tabi lati pada kuro lẹhin rẹ: nitori ibiti iwọ ba lọ, li emi o lọ; ibiti iwọ ba si wọ̀, li emi o wọ̀: awọn enia rẹ ni yio ma ṣe enia mi, Ọlọrun rẹ ni yio si ma ṣe Ọlọrun mi: Ibiti iwọ ba kú li emi o kú si, nibẹ̀ li a o si sin mi: ki OLUWA ki o ṣe bẹ̃ si mi, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi ohun kan bikoṣe ikú ba yà iwọ ati emi.