Rut 1:1-4

Rut 1:1-4 YBCV

O si ṣe li ọjọ́ wọnni ti awọn onidajọ nṣe olori, ìyan kan si mu ni ilẹ na. Ọkunrin kan lati Betilehemu-juda si lọ ṣe atipo ni ilẹ Moabu, on, ati obinrin rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin meji. Orukọ ọkunrin na a si ma jẹ́ Elimeleki, orukọ obinrin rẹ̀ a si ma jẹ́ Naomi, orukọ awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeji a si ma jẹ́ Maloni ati Kilioni, awọn ara Efrata ti Betilehemu-juda. Nwọn si wá si ilẹ Moabu, nwọn si ngbé ibẹ̀. Elimeleki ọkọ Naomi si kú; o si kù on, ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeji. Nwọn si fẹ́ aya ninu awọn obinrin Moabu; orukọ ọkan a ma jẹ́ Orpa, orukọ ekeji a si ma jẹ́ Rutu: nwọn si wà nibẹ̀ nìwọn ọdún mẹwa.