Rom 9:30-33

Rom 9:30-33 YBCV

Njẹ kili awa o ha wi? Pe awọn Keferi, ti kò lepa ododo, ọwọ́ wọn tẹ̀ ododo, ṣugbọn ododo ti o ti inu igbala wá ni. Ṣugbọn Israeli ti nlepa ofin ododo, ọwọ́ wọn kò tẹ̀ ofin ododo. Nitori kini? nitori nwọn ko wá a nipa igbagbọ́, ṣugbọn bi ẹnipe nipa iṣẹ ofin. Nitori nwọn kọsẹ lara okuta ikọsẹ ni; Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Kiyesi i, mo gbé okuta ikọsẹ ati àpata idugbolu kalẹ ni Sioni: ẹnikẹni ti o ba si gbà a gbọ, oju kì yio ti i.