Rom 9:24-26

Rom 9:24-26 YBCV

Ani awa, ti o ti pè, kì iṣe ninu awọn Ju nikan, ṣugbọn ninu awọn Keferi pẹlu? Bi o ti wi pẹlu ni Hosea pe, Emi ó pè awọn ti kì iṣe enia mi, li enia mi, ati ẹniti ki iṣe ayanfẹ li ayanfẹ. Yio si ṣe, ni ibi ti a gbé ti sọ fun wọn pe, Ẹnyin kì iṣe enia mi, nibẹ̀ li a o gbé pè wọn li ọmọ Ọlọrun alãye.