Rom 8:24-26

Rom 8:24-26 YBCV

Nitori ireti li a fi gbà wa là: ṣugbọn ireti ti a bá ri kì iṣe ireti: nitori tani nreti ohun ti o bá ri? Ṣugbọn bi awa ba nreti eyi ti awa kò ri, njẹ awa nfi sũru duro dè e. Bẹ̃ gẹgẹ li Ẹmí pẹlu si nràn ailera wa lọwọ: nitori a kò mọ̀ bi ã ti igbadura gẹgẹ bi o ti yẹ: ṣugbọn Ẹmí tikararẹ̀ nfi irora ti a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ fun wa.