Rom 8:22-25

Rom 8:22-25 YBCV

Nitori awa mọ̀ pe gbogbo ẹda li o jumọ nkerora ti o si nrọbi pọ̀ titi di isisiyi. Kì si iṣe awọn nikan, ṣugbọn awa tikarawa pẹlu, ti o ni akọ́so Ẹmí, ani awa tikarawa nkerora ninu ara wa, awa nduro dè isọdọmọ, ani idande ara wa. Nitori ireti li a fi gbà wa là: ṣugbọn ireti ti a bá ri kì iṣe ireti: nitori tani nreti ohun ti o bá ri? Ṣugbọn bi awa ba nreti eyi ti awa kò ri, njẹ awa nfi sũru duro dè e.