NJẸ ẹbi kò si nisisiyi fun awọn ti o wà ninu Kristi Jesu, awọn ti kò rìn nipa ti ara, bikoṣe nipa ti Ẹmí. Nitori ofin Ẹmí ìye ninu Kristi Jesu ti sọ mi di omnira lọwọ ofin ẹ̀ṣẹ ati ti ikú. Nitori ohun ti ofin kò le ṣe, bi o ti jẹ alailera nitori ara, Ọlọrun rán Ọmọ on tikararẹ̀ li aworan ara ẹ̀ṣẹ, ati bi ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ, o si da ẹ̀ṣẹ lẹbi ninu ara: Ki a le mu ododo ofin ṣẹ ninu awa, ti kò rin nipa ti ara, bikoṣe nipa ti Ẹmí. Nitori awọn ti o wà nipa ti ara, nwọn a mã ro ohun ti ara; ṣugbọn awọn ti o wà nipa ti Ẹmí, nwọn a mã ro ohun ti Ẹmí. Nitori ero ti ara ikú ni; ṣugbọn ero ti Ẹmí ni iye ati alafia: Nitori ero ti ara ọtá ni si Ọlọrun: nitori ki itẹriba fun ofin Ọlọrun, on kò tilẹ le ṣe e. Bẹ̃li awọn ti o wà ninu ti ara, kò le wù Ọlọrun. Ṣugbọn ẹnyin kò si ninu ti ara, bikoṣe ninu ti Ẹmí, biobaṣepe Ẹmí Ọlọrun ngbe inu nyin. Ṣugbọn bi ẹnikẹni kò ba ni Ẹmí Kristi, on kò si ninu ẹni tirẹ̀. Bi Kristi ba si wà ninu nyin, ara jẹ okú nitori ẹ̀ṣẹ: ṣugbọn ẹmí jẹ iyè nitori ododo. Ṣugbọn bi Ẹmí ẹniti o jí Jesu dide kuro ninu okú ba ngbe inu nyin, ẹniti o ji Kristi Jesu dide kuro ninu okú yio fi Ẹmí rẹ̀ ti ngbe inu nyin, sọ ara kikú nyin di ãye pẹlu. Njẹ nitorina, ara, ajigbèsè li awa, ki iṣe ara li a jẹ ni gbese, ti a o fi mã wà nipa ti ara. Nitori bi ẹnyin ba wà ni ti ara, ẹnyin ó kú: ṣugbọn nipa Ẹmí bi ẹnyin ba npa iṣẹ́ ti ara run, ẹnyin ó yè. Nitori iye awọn ti a nṣe amọ̀na fun lati ọdọ Ẹmí Ọlọrun wá, awọn ni iṣe ọmọ Ọlọrun.
Kà Rom 8
Feti si Rom 8
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Rom 8:1-14
5 Days
Prayer can sometimes seem lonely. Often, in prayer, I try to quiet my heart and soul, and my mind races everywhere. Sometimes I just fall asleep. There are times when it feels like my prayers bounce off the ceiling. What we often don’t realize, however, is that the Lord offers us good news right in these places. Let’s spend some time considering the good news about prayer.
7 Days
We're always told, "It's just another part of life," but trite sayings don't make the sting of losing a loved one any less painful. Learn to run to God when facing one of life's most difficult challenges.
There are at least seven major aspects of wholeness involved in seeking God’s best for your emotional life. You don’t need to take these in sequence. Join Dr. Charles Stanley as he helps you build key habits into your life that will help you become increasingly whole in your spirit and emotions. Discover more reading plans like this one at intouch.org/plans.
In a crowded Christmas season, most of us feel the stress and anxiety of family relationships, financial pressure, hasty decisions, and disappointed expectations. So go ahead. Take a breath. Start this Life.Church Bible Plan and realize the weight we feel may be something God never asked us to carry. How about we let go of the baggage? Let’s travel light.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò