Rom 7:4-8

Rom 7:4-8 YBCV

Bẹ̃li ẹnyin ará mi, ẹnyin pẹlu ti di okú si ofin nipa ara Kristi: ki ẹnyin kì o le ni ẹlomiran, ani ẹniti a jinde kuro ninu okú, ki awa ki o le so eso fun Ọlọrun. Nitori igbati awa wà nipa ti ara, ifẹkufẹ ẹ̀ṣẹ, ti o wà nipa ofin, o nṣiṣẹ ninu awọn ẹ̀ya ara wa lati so eso si ikú. Ṣugbọn nisisiyi a fi wa silẹ kuro ninu ofin, nitori a ti kú si eyiti a ti dè wa sinu rẹ̀: ki awa ki o le mã sìn li ọtun Ẹmí, ki o má ṣe ni ode ara ti atijọ. Njẹ awa o ha ti wi? ofin ha iṣe ẹ̀ṣẹ bi? Ki a má ri. Ṣugbọn emi kò ti mọ̀ ẹ̀ṣẹ, bikoṣepe nipa ofin: emi kò sá ti mọ̀ ojukokoro, bikoṣe bi ofin ti wipe, Iwọ kò gbọdọ ṣojukòkoro. Ẹ̀ṣẹ si ti ipa ofin ri aye, o ṣiṣẹ onirũru ifẹkufẹ ninu mi. Nitori laisi ofin, ẹ̀ṣẹ kú.