Rom 7:15-20

Rom 7:15-20 YBCV

Nitori ohun ti emi nṣe, emi kò mọ̀: nitori ki iṣe ohun ti mo fẹ li emi nṣe; ṣugbọn ohun ti mo korira, li emi nṣe. Ṣugbọn biobaṣepe ohun ti emi kò fẹ eyini li emi nṣe, mo gba pe ofin dara. Njẹ nisisiyi kì iṣe emi li o nṣe e mọ́, bikoṣe ẹ̀ṣẹ ti o ngbe inu mi. Nitori emi mọ̀ pe ko si ohun rere kan ti ngbe inu mi, eyini ninu ara mi: nitori ifẹ ohun ti o dara mbẹ fun mi, ṣugbọn ọna ati ṣe e li emi kò ri. Nitori ire ti emi fẹ emi kò ṣe: ṣugbọn buburu ti emi kò fẹ, eyini li emi nṣe. Ṣugbọn biobaṣepe ohun ti emi kò fẹ, eyini li emi nṣe, emi ki nṣe e mọ́, bikoṣe ẹ̀ṣẹ ti ngbe inu mi.