Njẹ ohun ti o dara ha di ikú fun mi bi? Ki a má ri. Ṣugbọn ẹ̀ṣẹ ki o le farahan bi ẹ̀ṣẹ o nti ipa ohun ti o dara ṣiṣẹ́ ikú ninu mi, ki ẹ̀ṣẹ le ti ipa ofin di buburu rekọja. Nitori awa mọ̀ pe ohun ẹmí li ofin: ṣugbọn ẹni ti ara li emi, ti a ti tà sabẹ ofin. Nitori ohun ti emi nṣe, emi kò mọ̀: nitori ki iṣe ohun ti mo fẹ li emi nṣe; ṣugbọn ohun ti mo korira, li emi nṣe. Ṣugbọn biobaṣepe ohun ti emi kò fẹ eyini li emi nṣe, mo gba pe ofin dara. Njẹ nisisiyi kì iṣe emi li o nṣe e mọ́, bikoṣe ẹ̀ṣẹ ti o ngbe inu mi. Nitori emi mọ̀ pe ko si ohun rere kan ti ngbe inu mi, eyini ninu ara mi: nitori ifẹ ohun ti o dara mbẹ fun mi, ṣugbọn ọna ati ṣe e li emi kò ri. Nitori ire ti emi fẹ emi kò ṣe: ṣugbọn buburu ti emi kò fẹ, eyini li emi nṣe. Ṣugbọn biobaṣepe ohun ti emi kò fẹ, eyini li emi nṣe, emi ki nṣe e mọ́, bikoṣe ẹ̀ṣẹ ti ngbe inu mi. Njẹ mo ri niti ofin pe, bi emi ti nfẹ lati mã ṣe rere, buburu a ma wà lọdọ mi.
Kà Rom 7
Feti si Rom 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Rom 7:13-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò