Rom 6:3-5

Rom 6:3-5 YBCV

Tabi ẹ kò mọ̀ pe, gbogbo wa ti a ti baptisi sinu Kristi Jesu, a ti baptisi wa sinu ikú rẹ̀? Njẹ a fi baptismu sinu ikú sin wa pọ̀ pẹlu rẹ̀: pe gẹgẹ bi a ti jí Kristi dide kuro ninu okú nipa ogo Baba bẹ̃ni ki awa pẹlu ki o mã rìn li ọtun ìwa. Nitori bi a ba ti so wa pọ̀ pẹlu rẹ̀ nipa afarawe ikú rẹ̀, a o si so wa pọ pẹlu nipa afarawe ajinde rẹ̀