Nitorina ẹ maṣe jẹ ki ẹ̀ṣẹ ki o jọba ninu ara kiku nyin, ti ẹ o fi mã gbọ ti ifẹkufẹ rẹ̀; Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ fun ẹ̀ṣẹ bi ohun elo aiṣododo; ṣugbọn ẹ jọwọ ara nyin lọwọ fun Ọlọrun, bi alãye kuro ninu okú, ati awọn ẹ̀ya ara nyin bi ohun elo ododo fun Ọlọrun. Nitori ẹ̀ṣẹ kì yio ni ipa lori nyin: nitori ẹnyin kò si labẹ ofin, bikoṣe labẹ ore-ọfẹ. Njẹ kini? ki awa ki o ha ma dẹṣẹ̀, nitoriti awa kò si labẹ ofin, bikoṣe labẹ ore-ọfẹ? Ki a má ri. Ẹnyin kò mọ̀ pe, ẹniti ẹnyin ba jọwọ ara nyin lọwọ fun bi ẹrú lati mã gbọ́ tirẹ̀, ẹrú ẹniti ẹnyin ba gbọ tirẹ̀ li ẹnyin iṣe; ibãṣe ti ẹ̀ṣẹ sinu ikú, tabi ti igbọran si ododo? Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun pe, bi ẹnyin ti jẹ ẹrú ẹ̀ṣẹ rí, ẹnyin jẹ olugbọran lati ọkàn wá si apẹrẹ ẹkọ ti a fi nyin le lọwọ. Bi a si ti sọ nyin di omnira kuro ninu ẹ̀ṣẹ, ẹnyin di ẹrú ododo. Emi nsọ̀rọ bi enia nitori ailera ara nyin: nitori bi ẹnyin ti jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ bi ẹrú fun iwa-ẽri ati fun ẹ̀ṣẹ de inu ẹ̀ṣẹ; bẹ̃ gẹgẹ ni ki ẹnyin ki o jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ nisisiyi bi ẹrú fun ododo si ìwa-mimọ́. Nitori nigbati ẹnyin ti jẹ ẹrú ẹ̀ṣẹ, ẹnyin wà li omnira si ododo. Njẹ eso kili ẹnyin ha ni nigbana ninu ohun ti oju ntì nyin si nisisiyi? nitori opin nkan wọnni ikú ni. Ṣugbọn nisisiyi ti a sọ nyin di omnira kuro ninu ẹ̀ṣẹ, ti ẹnyin si di ẹrú Ọlọrun, ẹnyin ni eso nyin si ìwa mimọ́, ati opin rẹ̀ ìye ainipẹkun. Nitori ikú li ère ẹ̀ṣẹ; ṣugbọn ẹ̀bun ọfẹ Ọlọrun ni ìye ti kò nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa.
Kà Rom 6
Feti si Rom 6
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Rom 6:12-23
7 Days
There are at least seven major aspects of wholeness involved in seeking God’s best for your emotional life. You don’t need to take these in sequence. Join Dr. Charles Stanley as he helps you build key habits into your life that will help you become increasingly whole in your spirit and emotions. Discover more reading plans like this one at intouch.org/plans.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò