Rom 5:15-17

Rom 5:15-17 YBCV

Ṣugbọn kì iṣe bi ẹ̀ṣẹ bẹ̃ si li ẹ̀bun ọfẹ. Nitori bi nipa ẹ̀ṣẹ ẹnikan, ẹni pupọ kú, melomelo li ore-ọfẹ Ọlọrun, ati ẹ̀bun ninu ore-ọfẹ ọkunrin kan, Jesu Kristi, di pupọ fun ẹni pupọ. Kì isi ṣe bi nipa ẹnikan ti o ṣẹ̀, li ẹ̀bun na: nitori idajọ ti ipasẹ ẹnikan wá fun idalẹbi ṣugbọn ẹ̀bun ọfẹ ti inu ẹ̀ṣẹ pupọ wá fun idalare. Njẹ bi nipa ẹ̀ṣẹ ọkunrin kan ikú jọba nipasẹ ẹnikanna; melomelo li awọn ti ngbà ọ̀pọlọpọ ore-ọfẹ ati ẹ̀bun ododo yio jọba ninu ìye nipasẹ ẹnikan, Jesu Kristi.