Rom 4:20-25

Rom 4:20-25 YBCV

Kò fi aigbagbọ ṣiyemeji ileri Ọlọrun; ṣugbọn o le ni igbagbọ́, o nfi ogo fun Ọlọrun; Nigbati o sa ti mọ̀ dajudaju pe, ohun ti on ba ti leri, o si le ṣe e. Nitorina li a si ṣe kà a si ododo fun u. A kò sá kọ ọ nitori tirẹ̀ nikan pe, a kà a si fun u, Ṣugbọn nitori tiwa pẹlu, ẹniti a o si kà a si fun, bi awa ba gbà a gbọ́, ẹniti o gbé Jesu Oluwa wa dide kuro ninu okú; Ẹniti a fi tọrẹ ẹ̀ṣẹ wa, ti a si jinde nitori idalare wa.