Rom 4:19-21

Rom 4:19-21 YBCV

Ẹniti kò ṣe ailera ni igbagbọ́, kò rò ti ara on tikararẹ̀ ti o ti kú tan (nigbati o to bi ẹni ìwọn ọgọrun ọdún), ati kíku inu Sara: Kò fi aigbagbọ ṣiyemeji ileri Ọlọrun; ṣugbọn o le ni igbagbọ́, o nfi ogo fun Ọlọrun; Nigbati o sa ti mọ̀ dajudaju pe, ohun ti on ba ti leri, o si le ṣe e.