(Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Mo ti fi ọ ṣe baba orilẹ-ède pupọ,) niwaju ẹniti on gbagbọ́, Ọlọrun tikararẹ̀, ti o sọ okú di ãye, ti o si pè ohun wọnni ti kò si bi ẹnipe nwọn ti wà; Nigbati ireti kò si, ẹniti o gbagbọ ni ireti ki o le di baba orilẹ-ède pupọ, gẹgẹ bi eyi ti a ti wipe, Bayi ni irú-ọmọ rẹ yio ri. Ẹniti kò ṣe ailera ni igbagbọ́, kò rò ti ara on tikararẹ̀ ti o ti kú tan (nigbati o to bi ẹni ìwọn ọgọrun ọdún), ati kíku inu Sara: Kò fi aigbagbọ ṣiyemeji ileri Ọlọrun; ṣugbọn o le ni igbagbọ́, o nfi ogo fun Ọlọrun; Nigbati o sa ti mọ̀ dajudaju pe, ohun ti on ba ti leri, o si le ṣe e. Nitorina li a si ṣe kà a si ododo fun u.
Kà Rom 4
Feti si Rom 4
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Rom 4:17-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò