Nitori ohunkohun ti a ti kọ tẹlẹ, a ti kọ ọ fun kíkọ wa, pe nipa sũru ati itunu iwe-mimọ́ ki a le ni ireti. Njẹ ki Ọlọrun sũru ati itunu ki o fi fun nyin lati ni inu kan si ara nyin gẹgẹ bi Kristi Jesu: Ki ẹnyin ki o le fi ọkàn kan ati ẹnu kan yìn Ọlọrun, Baba Jesu Kristi Oluwa, logo. Nitorina ẹ gbá ara nyin mọra, gẹgẹ bi Kristi ti gbá wa mọra fun ogo Ọlọrun. Mo si wipe, a ti fi Jesu Kristi ṣe iranṣẹ ikọla nitori otitọ Ọlọrun, ki o ba le mu awọn ileri na duro ti a ti ṣe fun awọn baba, Ati ki awọn Keferi ki o le yìn Ọlọrun logo nitori ãnu rẹ̀; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Nitori eyi li emi ó ṣe yin ọ lãrin awọn Keferi, emi o si kọrin si orukọ rẹ.
Kà Rom 15
Feti si Rom 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Rom 15:4-9
7 Days
How can we find the right attitude for every situation? What is the right attitude? This seven-day Bible Plan finds answers in the life and teachings of Christ. Let these daily encouragements, reflective prayers, and powerful Scriptures form in you the mind of Christ.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò