Rom 15:19-22

Rom 15:19-22 YBCV

Nipa agbara iṣẹ-àmi ati iṣẹ-iyanu, nipa agbara Ẹmí Ọlọrun; tobẹ̃ lati Jerusalemu ati yiká kiri ani titi fi de Illirikoni, mo ti wasu ihinrere Kristi ni kikun. Mo du u lati mã wasu ihinrere na, kì iṣe nibiti a gbé ti da orukọ Kristi ri, ki emi ki o máṣe mọ amọle lori ipilẹ ẹlomiran. Ṣugbọn gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Awọn ẹniti a kò ti sọ̀rọ rẹ̀ fun, nwọn ó ri i: ati awọn ti kò ti gbọ́, òye yio yé wọn. Nitorina pẹlu li àye ṣe há fun mi li akoko wọnyi lati tọ̀ nyin wá.