Rom 14:13-23

Rom 14:13-23 YBCV

Nitorina ẹ máṣe jẹ ki a tun mã da ara wa lẹjọ mọ́: ṣugbọn ẹ kuku mã ṣe idajọ eyi, ki ẹnikẹni máṣe fi ohun ikọsẹ tabi ohun idugbolu si ọ̀na arakunrin rẹ̀. Mo mọ̀, o si dá mi loju ninu Jesu Oluwa pe, kò si ohun ti o ṣe aimọ́ fun ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o ba kà ohunkohun si aimọ́, on li o ṣe aimọ́ fun. Ṣugbọn bi inu arakunrin rẹ ba bajẹ nitori onjẹ rẹ, njẹ iwọ kò rìn ninu ifẹ mọ́. Ẹniti Kristi kú fun, máṣe fi onjẹ rẹ pa a kúgbe. Njẹ ẹ máṣe jẹ ki a mã sọ̀rọ ire nyin ni buburu. Nitori ijọba Ọlọrun kì iṣe jijẹ ati mimu; bikoṣe ododo, ati alafia, ati ayọ̀ ninu Ẹmí Mimọ́. Nitori ẹniti o ba nsìn Kristi ninu nkan wọnyi, li o ṣe itẹwọgbà lọdọ Ọlọrun, ti o si ni iyin lọdọ enia. Njẹ nitorina, ki awa ki o mã lepa ohun ti iṣe ti alafia, ati ohun ti awa o fi gbe ara wa ró. Nitori onjẹ máṣe bi iṣẹ Ọlọrun ṣubu. Ohun gbogbo li o mọ́ nitõtọ; ṣugbọn ibi ni fun oluwarẹ̀ na ti o njẹun lọna ikọsẹ. O dara ki a má tilẹ jẹ ẹran, ki a má mu waini, ati ohun kan nipa eyi ti arakunrin rẹ yio kọsẹ, ati ti a o si fi sọ ọ di alailera. Iwọ ní igbagbọ́ bi? ní i fun ara rẹ niwaju Ọlọrun. Alabukun-fun ni oluwarẹ̀ na ti ko da ara rẹ̀ lẹbi ninu ohun ti o yàn. Ṣugbọn ẹniti o ba nṣiyemeji, o jẹbi bi o ba jẹ, nitoriti kò ti inu igbagbọ́ wá: ati ohunkohun ti kò ti inu igbagbọ wá, ẹṣẹ ni.