Rom 14:10-12

Rom 14:10-12 YBCV

Ṣugbọn ẽṣe ti iwọ fi nda arakunrin rẹ lẹjọ? tabi ẽsitiṣe ti iwọ fi nkẹgan arakunrin rẹ? gbogbo wa ni yio sá duro niwaju itẹ́ idajọ Kristi. Nitori a ti kọ ọ pe, Oluwa wipe, Bi emi ti wà, gbogbo ẽkún ni yio kunlẹ fun mi, ati gbogbo ahọn ni yio si jẹwọ fun Ọlọrun. Njẹ nitorina, olukuluku wa ni yio jihin ara rẹ̀ fun Ọlọrun.