Rom 14:1-5

Rom 14:1-5 YBCV

ṢUGBỌN ẹniti o ba ṣe ailera ni igbagbọ́ ẹ gbà a, li aitọpinpin iṣiyemeji rẹ̀. Ẹnikan gbagbọ́ pe on le mã jẹ ohun gbogbo: ẹlomiran ti o si ṣe alailera njẹ ewebẹ. Ki ẹniti njẹ máṣe kẹgan ẹniti kò jẹ; ki ẹniti kò si jẹ ki o máṣe dá ẹniti njẹ lẹjọ: nitori Ọlọrun ti gbà a. Tani iwọ ti ndá ọmọ-ọdọ ẹlomĩ lẹjọ? loju oluwa rẹ̀ li o duro, tabi ti o ṣubu. Nitotọ a o si mu u duro: nitori Oluwa ni agbara lati mu u duro. Ẹlomĩ mbuyìn fun ọjọ kan jù omiran lọ: ẹlomĩ mbuyìn fun ọjọ gbogbo bakanna. Ki olukuluku ki o da ara rẹ̀ loju ni inu ara rẹ̀.