Njẹ mo wi fun olukuluku enia ti o wà ninu nyin, nipa ore-ọfẹ ti a fifun mi, ki o máṣe rò ara rẹ̀ jù bi o ti yẹ ni rirò lọ; ṣugbọn ki o le rò niwọntun-wọnsìn, bi Ọlọrun ti fi ìwọn igbagbọ́ fun olukuluku. Nitori gẹgẹ bi awa ti li ẹ̀ya pipọ ninu ara kan, ti gbogbo ẹ̀ya kò si ni iṣẹ kanna: Bẹ̃li awa, ti a jẹ́ pipọ, a jẹ́ ara kan ninu Kristi, ati olukuluku ẹ̀ya ara ọmọnikeji rẹ̀. Njẹ bi awa si ti nri ọ̀tọ ọ̀tọ ẹ̀bun gbà gẹgẹ bi ore-ọfẹ ti a fifun wa, bi o ṣe isọtẹlẹ ni, ki a mã sọtẹlẹ gẹgẹ bi ìwọn igbagbọ́; Tabi iṣẹ-iranṣẹ, ki a kọjusi iṣẹ-iranṣẹ wa: tabi ẹniti nkọ́ni, ki o kọjusi kíkọ́; Tabi ẹniti o ngbàni niyanju, si igbiyanju: ẹniti o nfi funni ki o mã fi inu kan ṣe e; ẹniti nṣe olori, ki o mã ṣe e li oju mejeji; ẹniti nṣãnu, ki o mã fi inu didùn ṣe e. Ki ifẹ ki o wà li aiṣẹtan. Ẹ mã takéte si ohun ti iṣe buburu; ẹ faramọ́ ohun ti iṣe rere. Niti ifẹ ará, ẹ mã fi iyọ́nu fẹran ara nyin: niti ọlá, ẹ mã fi ẹnikeji nyin ṣaju. Niti iṣẹ ṣiṣe, ẹ má ṣe ọlẹ; ẹ mã ni igbona ọkàn; ẹ mã sìn Oluwa; Ẹ mã yọ̀ ni ireti; ẹ mã mu sũru ninu ipọnju; ẹ mã duro gangan ninu adura
Kà Rom 12
Feti si Rom 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Rom 12:3-12
3 Days
If voices of insecurity, doubt, and fear are not confronted, they will dictate your life. You cannot silence these voices or ignore them. In this 3-day reading plan, Sarah Jakes Roberts shows you how to defy the limitations of your past and embrace the uncomfortable to become unstoppable.
21 Days
In the 21 Days to Overflow YouVersion plan, Jeremiah Hosford will take readers on a 3-week journey of emptying themselves of themselves, being filled with the Holy Spirit, and living out an overflowing, Spirit-filled life. It’s time to stop living normally and start living an overflowing life!
7 Awọn ọjọ
Igbe Ayé Kristeni kii ṣe ìgbé Ayé irọrun, ọrọ àti itẹlọrun ní gbogbo ìgbà ṣugbọn ojẹ ìgbé Ayé Ìrúbọ ati ìsìn. Jésù wá sí ayé láti wá fi àpẹẹrẹ náà hàn fún wa láti ri. Jésù wá, o gbè ìgbé Ayé isẹrà ẹni, aimọtàrà ẹni nikan, iyasọtọ, iwọntunwọnsi ati ìrúbọ titi ti O fi kù fún ìràpadà wá. Ìdí yii ni àfi ni àkọsílẹ̀ rẹ ninú awọn ìwé ìhìnrere.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò