NITORINA mo fi iyọ́nu Ọlọrun bẹ̀ nyin, ará, ki ẹnyin ki o fi ara nyin fun Ọlọrun li ẹbọ ãye, mimọ́, itẹwọgbà, eyi ni iṣẹ-isìn nyin ti o tọ̀na. Ki ẹ má si da ara nyin pọ̀ mọ́ aiye yi: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun ni iro-inu nyin, ki ẹnyin ki o le ri idi ifẹ Ọlọrun, ti o dara, ti o si ṣe itẹwọgbà, ti o si pé. Njẹ mo wi fun olukuluku enia ti o wà ninu nyin, nipa ore-ọfẹ ti a fifun mi, ki o máṣe rò ara rẹ̀ jù bi o ti yẹ ni rirò lọ; ṣugbọn ki o le rò niwọntun-wọnsìn, bi Ọlọrun ti fi ìwọn igbagbọ́ fun olukuluku. Nitori gẹgẹ bi awa ti li ẹ̀ya pipọ ninu ara kan, ti gbogbo ẹ̀ya kò si ni iṣẹ kanna: Bẹ̃li awa, ti a jẹ́ pipọ, a jẹ́ ara kan ninu Kristi, ati olukuluku ẹ̀ya ara ọmọnikeji rẹ̀.
Kà Rom 12
Feti si Rom 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Rom 12:1-5
3 Days
If voices of insecurity, doubt, and fear are not confronted, they will dictate your life. You cannot silence these voices or ignore them. In this 3-day reading plan, Sarah Jakes Roberts shows you how to defy the limitations of your past and embrace the uncomfortable to become unstoppable.
7 Awọn ọjọ
Igbe Ayé Kristeni kii ṣe ìgbé Ayé irọrun, ọrọ àti itẹlọrun ní gbogbo ìgbà ṣugbọn ojẹ ìgbé Ayé Ìrúbọ ati ìsìn. Jésù wá sí ayé láti wá fi àpẹẹrẹ náà hàn fún wa láti ri. Jésù wá, o gbè ìgbé Ayé isẹrà ẹni, aimọtàrà ẹni nikan, iyasọtọ, iwọntunwọnsi ati ìrúbọ titi ti O fi kù fún ìràpadà wá. Ìdí yii ni àfi ni àkọsílẹ̀ rẹ ninú awọn ìwé ìhìnrere.
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò