Rom 11:1-4

Rom 11:1-4 YBCV

NJẸ mo ni, Ọlọrun ha ta awọn enia rẹ̀ nù bi? Ki a má ri. Nitori Israeli li emi pẹlu, lati inu irú-ọmọ Abrahamu, li ẹ̀ya Benjamini. Ọlọrun kò ta awọn enia rẹ̀ nù ti o ti mọ̀ tẹlẹ. Tabi ẹnyin kò mọ̀ bi iwe-mimọ́ ti wi niti Elijah? bi o ti mbẹ̀bẹ lọdọ Ọlọrun si Israeli, wipe, Oluwa, nwọn ti pa awọn woli rẹ, nwọn si ti wó awọn pẹpẹ rẹ lulẹ; emi nikanṣoṣo li o si kù, nwọn si nwá ẹmí mi. Ṣugbọn idahun wo li Ọlọrun fifun u? Mo ti kù ẹ̃dẹ́gbãrin enia silẹ fun ara mi, awọn ti kò tẹ ẽkun ba fun Baali.